ISEDALE ILU OYO

Imujade lati Inu ise Iwadi  Ijinle Omoba Adeyemi Olabimpe  (Akojopo ati tite lati owo alamojuto oro iroyin arakun Oladotun Oladele 08037250845)

Awon eya Yoruba ti o side leyin ti Oduduwa ti fidi mule si Ile-Ife po pupo. Lara won ni Owu, Oyo, Ketu, Egba, Ijebu, Ijesa, Sabee, Popo, Ignomina abbi. Ohun kan ti a saba fi  da eya kan mo so omiran, ni agbegbe ibi to won tedo si, ede abinibi ti won n so, ise to wopo laarin won ti won n se, Orisa to fidii mule laarin won ti won n bo, ounje ti won n je ati ohun ogbin ti won n saba gbin pelu ihuwa ati ibagbepo won.

Ninu gbogbo eya tabi ijoba Ile Yoruba, eyi ti o tobi ju ni Oyo. Oranmiyan ti o te Oyo do je jagunjagun, ikanniko, Oloogun ati Akanda eniyan gege bi Oduduwa. Itan so fun ni pe, oun naa jade kuro ni Ile-Ife, o si gun esin jade ni ati pe, Ifa ni ibi ti ese esin re ba yo ni ki o tedo si, ibi ti esin re ti yo yii ni a n pe ni “ÒYÓ”. Ni iha iwo-oorun, Oranmiyan ni a ri ti o se bi i baba re ti o le pa gbogbo awon ilu kereje abe re po si abe ijoba kan soso tii se tie.

Adeoye (1979) ni, Oranmiyan ni o Koko da Eso sile, oun si ni olori awon Eso ni ile Yoruba ni akoko tie. O fi kun un pe, nitori ti o je olori awon Eso yi ati jagunjagun ti o kaju osuwon ni afefe yeye awon Oyo se po, eyi ni won si fi maa nse yanga si awon omo baba won yooku, ti won maa n powe pe “A-ji-se-bi-Oyo la a ri, Oyo ki i se bi enikan”. Titi di oni ni okiki Oranmiyan kan ni ile-Ife koda bi a ba ti mu odun Oduduwa sise kuro ni Ife tan, odun ti o tun se pataki bi i ti Oranmiyan ko si mo ni aarin awon Yoruba.

Kete ti Oranyan de Oyo-Ile ni o yan awon Iwarefa, awon mefeefa ohun naa ni Basorun, Agbaakin, Samu, Alapiinni, Laguna ati Akinniku. Nigba ti o ya ni oruko yii awon Iwarefa yii si yipada di “Oyo-mesi” asiko naa si ni awon Iwarefa yii kuro ni mefa ti won di meje pelu afikun “Asipa”.

J.F.A. Ajayi ati S.A. Akintoye (1980) so pe, àgbàrá Oyo po lasiko naa debi pe, ki i se Ile Oyo nikan ni o lagbara le Lori, o tun lagbara lori awon ilu ti o wa lagbegbe re ati awon ti o baa paala bi i Borgu, Nupe, Egba ati Egbado, dahomi pelu Potu-Nofo (Porto-Novo). Ona ti o se pataki ju ti awon onisowo lati Bini si Owo, Akure lo si Naija n gba si tun koja si Oyo.

Eyi waa je ki o je pe, ninu gbogbo Ile Yoruba pata ni ibere senturi kokandilogun (19th century), won gba Ife gege bi orirun Yoruba ati paapaa Ile awon ti o te Ile Yoruba do. Won fun Oyo ni Owo pupo nitori àgbàrá ati owo ti won ni lasiko naa, ati pelu eto isejoba won ti o muna doko ti o si fese rinle gbingbin.

Nigba ti o se, àgbàrá Oyo po debi pe o soro fun Alaafin lati sakoso ilu ohun, awon ijoye ko dun un sejoba le lori mo, o si soro fun Oba lati fokan tan won deny. Akinjogbin (1966) je ki o yeni pe, pelu bi Alaafin ati awon Ijoye ko se gbo ara won ye yii fi Aaye sile fun ote lati wo inu ijoba Oyo, se bi ogiri ko ba lanu, alangba ko le raye wo o.

Gbogbo ogbon ati eye lati pana awon aawo yi ja si pabo, eyi si je ki ogun raye ja Oyo, ote ati tembelekun wole, ilu Oyo si tu ni eyi ti o mu ki ijoba Oyo sipopada si Oyo-Igboho. Alaafin merin ni o je ni ilu Oyo-Igboho, awon mereerin ni won si sun si ibi ti a n pe ni “Igbo-Oba” ni ilu ohun bayii. Oruko awon Alaafin naa ni Alaafin Ofiran, Alaafin Egun-oju, Alaafin Orompoto ati Alaafin Ajiboyede.

Leyin ti Alaafin Ajiboyede papoda ni Omo re ti n je Tella Abipa bo sori oye, oun ni o si gbe ijoba Oyo kuro ni Oyo-Igboho to o si pada gbe lol si ibi ti mo si Oyo-Ile ti i se Ibujoko Oyo tele.

Ogun abele lorisiirisi ni ilu Oyo ati it’s tabi lati of awon ilu ti won n fe ominira ara won lo pada tu Oyo-Ile paapaa julo ogun awon Fulani Ilorin. Akosile R.C.C. Law (1971) Fi han pe awon ogun wonyi lo bi Oyo-Ile wo patapata ni nnkan bi i odun 1836. Leyin isele yii ni ijoba Oyo tun lol tedo si ibi ti a mo si Ago-d’Oyo pelu iranlowo Atiba ti o koko je ni Oyo Yi. Ago-d’Oyo yii si ni Ijoba Oyo fidi mule si titi di oni.

Ti a ba wa n soro lonii ni pa Oyo tuntun yii, paapaa julo nipa awon Alaafin ibe, ori Alaafin Atiba ti o je akoko Oba nibe laarin odun 1837 si 1859 ni a ti maa bere, ibe naa ni a o si setupale lori iwadii nipa Oriki won titi di ori Alaafin toni Oba Adeyemi keta. (Ti won sese waaja)

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *