ETO ISELU OYO

Akorojo Oladotun Oladele 08037250845, Adari Iroyin Alaafin Oyo)

Ni Ile kaaaro-oo-jire, ninu Ilana iselu won, Oba ni o wa ni ipekun àgbàrá. Ti Oba l’ase, Oba lol nile, oun lo lade ori, ka bii ko so, ohun ti Oba ba se ti di asegbe. Yoruba ka Oba SI eniyan oto ti a gbe ida ase le lowo lati owo Olodumare, agbara ti enikan ki i yewo lol wa lowo Oba pelu.

Ni ilu Oyo, Oba nikan ki i se ilu, o ni awon Ijoye kan ti a n pe ni “Oyo-Mesi”, Basorun si ni olori won. Awon omo igbimo yii je Oloye to ga julo ni ilu, okookan so maa n je asoju idile kookan. Olubadamoran oba ni won, saasa si ni ohun ti Oba le se leyin won lai bun won gbo. Ti awon Ijoye wonyi ba ti ipade igbimo de, won maa n Jose fun awon eniyan won. Won le se eyi nipa pipe awon baale tabi olori-ebi ki won si fi ohun ti won fenuko le lori to won leti. Iwonyi kan naa ni awon ara ilu maa n gba so nnkan ti won ba fee so fun Oba.

Ewe, yato si awon Ijoye Alaafin bawonyi, agboole kookan loni awon baale lorisiirisii tabi olori ebi nibomiran. Iyato ti o wa laarin awon Ijoye ilu ati awon olori ebi yii ni pe, oba maa fowo so yiyab awon Ijoye ilu won si maa n ni oruko oye tiwon sugbon ni ti olori ebi, a ki i daruko, ki i si i se ohun ti Oba le fenu si yiyan re, eni ti o ba kan la maa n fun.

Ise takuntakun ni baale ile maa n se paapaa lori isakoso ati igbejo pelu atileyin awon agba to wa ninu ebi bee ni yoo maa se amojuto agbegbe re, pipari ija wa lara ise ti o maa n se tabi aawo laaarin awon eniyan idile. O le ni igbejo ara re. Sugbon, ko le mu eni to ba jebi sanwo itanran, ohun ti o maa n se ninu idajo ki i ju ki agboole re wa laalaafia ati ni isokan lo. Bi oro tile ri bayii, o maa n mu eni to ba je odaran paraku jiya nile ejo.

Leyin baale ile ni o kan Oloye adugbo. Oun naa maa n ri i pe, alaafia j’oba ni adugbo re, oun ni agbenuso won ninu eto ijoba ilu. O se e se ki o ni ile igbejo kan san-an ti o kan yato si to baale, o si le da si ejo ti o ba je mo to awon eniyan ni agboole re, won le fiya je odaran, o si le mu ki eni to ba jebi san Owo itanran sugbon, ejo ti o ba je mo ole paraku, yoo se iwadi re finnifinni ki o too fi to awon igbimo oba leti.

Oba le se amugboro ijoba re nipa side amulo awon ilu to wa ni agbegbe re. Eto isakoso onipele yii fi han wi pe, orisiirisii ni awon akopa to wa ninu igbimo naa. Ohun to maa n to ibe jade ni pe ijoba tiwa-n-tiwa lo n sele ni ilu, ki i saba si ipinya laarin ijoba ati ara ilu, eyi lo mu ki awon ara ilu ma fowosowopo pelu oba ati Ijoye niwon igba ti eto isakoso tele ofin to gbogbo Ile.

Ohun ti a n so yii yoo di mimo, yoo si yeni yekeyeke ti a ba mo bi awon ara ilu se maa n se atileyin fun ijoba. Late ojohun, oba kii gba owo osu sine, oba ki i tawona bee ni ki taraka ko too jeun, kii si tile se alaini ohun to dara, se ni aafin oba dabi Ile fun gbogbo ara ilu, idi niyi ti o fi je pe, gbogbo ara ilu ni o maa n pawopo ko aafin oba. Irufe ise ilu to je afoogub oju se wonyi je ona miiran lati fi han pe eto isakoso ijoba Oyo wuyi pupo.

Olukuluku molebi tabi omo adugbo lo maa n se alabojuto enikeji re, eyi lo fa a ti awon iwa palapala to gbode kan lawujo l’ode oni ko fi bee wopo nile Yoruba debi pe too di wahala fun won to si fa a ti alaafia ati ifokanbale fi was nile Oyo titi di oni.

Die lara awon eto ti o wa niluu Oyo late ojohun tun ni pimpin ile Oyo si ona merin lati mu ki eto isakoso rorun, Alaafin si yan alakoso fun ekun kookan. Awon ekun naa ni:

A. Ekun Osi: Ikoyi, alaboojuto ni Onikoyi; Igbon ni Olugbon; Iresa ni Aresa.

B. Ekun Otun: Awon wonyi ni ilu Oke Ogun, Oke-Iho, Saki, Igboho, Ipapo, Kisi, Iseyin, Ado-Awaye, Eruwa, Oke, Sabiganna ni olori alamojuto awon ilu wonyi.

D. Ekun Ibolo: Awon eniyan ti o wa ni ekun yii ni awon ti o n so “Mo je be, mo mu be, n be n be”. Timi Agbale Olofa Ina ni alamoojuto ekun yii.

E. Ekun Epo: Die ninu awon ilu ekun yi ni Iwo, Idese, Telemu, Ogbaagbaa. Oluwo ni alamoojuto agbegbe yii. Igbo ni Ekun Epo yii ni aye atijo, ko si tii si ilu ti a n pe ni Ibadan lonii.

Onikaluku awon alamoojuto yi gege bi oruko won ni o nilati mojuto ekun re ki o si je ki Alaafin maa mo ohun ti o nlo ni ekun re. Ewe, o han gbangba pe, awon Ijoye ni oba n lo lati se eto ilu, o si tun han gbangba pe, a fun won ni anfani ati lo awon atunluuse, oselu ati ojelu, a ko si ko oka awon borokinni ati odo ilu kere nitori pe, “Omode gbon Agba gbon ni a fi da Ile-Ife”. Irufe eto yii ni o si je ki a maa pa a lowe pe, “oku ejo ni oloja a da”, eyi ti o so oba di asorose ti ki so oro o ti.

Bi eyi tile re bee, eto Ajeje owo kan ko gberu dori ni oba n lo, agbajo owo ti a fi n so aya si ni agbara ti Oba ni.

(E se, e ku suru, eku kika, e de tun ku oju lona fun akotun omiran to tun nbo lona)

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *