ATUPALE ORIKI ALAAFIN LAMIDI OLAYIWOLA ADEYEMI KETA

(Oladotun Oladele 08037250845)

Omoba Lamidi Adeyemi ati Omoba Bello Sanda Adeyemi ni won jo du ipo Alaafin leyin ti Oba Gbadegesin papoda pelu awon mejila miiran. Idile Alowolodu ti Oba kan fenuko yan omoba Sanda to won si fi oruko re ranse si awon igbimo Oyo-Mesi pelu awon toku. Marun-un ninu awon igbimo meje yii ni won dibo fun omoba Adeyemi ti won si fi ranse si ijoba lai beau begba.

Ohun ti o se e se ki o fa eyi ni ipo ti awon Alaafin isaju ti wa latari aikawe won. Awon Ajele Oyinbo ti bere si ni gbe ori fun awon oba miiran ti won kawe gege bi Ooni to Ile-Ife, Alake Egba, won si ti n yan won ni asoju nile igbimo lobaloba nitori aileko tabi ka awon Alaafin isaju. Tori bee, awon afobaje ri idi pataki lati Yan oba to mowe, Omoba Sand ko si ka ju ile-iwe alakoobere lo. Eyi ni won fi n ki Alaafin Adeyemi keta pe:

A ti n jobs loyoo ojo pe 

A o ti joba to mowe l’Alaafin 

Bi i ti Layiwola, Atanda 

Atanda mowe, o mo tia 

Atanda baba Kudi 

Oba lomo Adeyemi.

Yato si awon Oyo-Mesi, awon Oyo parapo ati awon pupo omo Oyo lo fowo si yiyan omoba Olayiwola ni pataki nitori ti o kere lojo ori ati paapaa yoo le san oju apa ti yiyo baba a re Fi sile.

Ewe, opolopo atako ni Alaafin Adeyemi keta ni latari oye ti o je. Yato si meji ninu awon Oyo-mesi ti ko faramo yiyan  an re, awon ti o fi oruko omoba Sanda ranse, ni idile Alowolodu ko dake rara won si san gbogbo ona lati ri i pe ko de ori ipo oba bi i Kiko iwe ipenija, iwe ejo, ifehonuhan ati bee bee lol. Lori eyi ni won fi n ki i pe:

Layiwola, oba lomo Lawoyin 

Won kowe ibaba 

Won kowe ikoko 

Kabiyesi, afobaje 

Ni o gboroo ti won.

Leyin ti won fi Alaafin Adeyemi keta joba tan, awon omoba lorisiirisii ati olori ebi Alowolodu parapo se atileyin fun in. Won si gba a loba. Tori bee ni won se ki Alaafin Adeyemi keta nigba naa ni:

Abata-se-keeke-gbale 

Won difa difa 

Owo o won dawo 

Won saagun saagun 

Ereke won Dapo 

Igba sigidi o r’Atanda 

Layiwola ni e ma s’amo lofo mo 

Layioye oba lomo Adeyemi.

Asiko ti Alaafin je oba yii ti o pa menu awon ota ati alatako mo ni awon onkorin fi n ki bayii pe:

Eni  a tee, tee, tee, t’Olorun o te 

Eni a buku, buku, t’Olorun o buku 

Eni won ka lese mejeeji 

T’Olorun o je o subu 

O se bi ere bi ere 

O pele lorii gbogbo won 

Igba tuuba 

Awo tuuba 

Isasun to loun o nii tuuba

Layiwola, ina o foju e ri mabo.

Latari iko alejo mora ati eni ife ti Alaafin Adeyemi keta ni si gbogbo mutumuwa ni won fi n ki i pe:

Ki i b’alejo pe nibo lo ti wa? 

O l’aso to kari gbogbo alagbe.

Bakan naa, nitori iseda re ti o je enikan ti ko sanra tabi tobi rara nigba naa ni awon apohun fi maa n pe e ni:

Opeere o to yankolo 

Omo Asiawu.

Fun ewa, awo tun wo omokunrin, awon onkorino wn ma n ki won pe:

Eni obinrin ko lona to n rererin muse to ni bi eleyi o ba je oko eni a si je ale eni

Arodorodo abaja 

Ayungba yungba akeyinsi

 Fun Ogbon atinuda Atanda won nma n korin wipe:

Bo ba n wo sun bi eniti ko logbon ninu

Lamidi atanda n wo gbogbo e lokookan ni o ri ohun ti kaluku won n se

Orun dake bi eni ti ki ro ojo

Dundun fi oro gbogbo se apamora

Afi oro ogun odun se

 akawewo

Tio tio to n tenu moran.

Leave a Reply

Your email address will not be published. Required fields are marked *